AJÁ O̩DE̩
Bí a ró̩mo̩ nís̩é̩ e̩rú
s̩ebí ìye̩n a fi to̩mo̩ jé̩ e̩
Àwo̩n àgbà kan, àgbà kàn ló̩jó̩sí
s̩é àwo̩n ló so̩ pé
àgbàtán làá gbò̩le̩,
bá a gbè é níjà, à á sìn-ín délé
bá a fún-un lás̩o̩, à á pá láró ni
bí ò̩rò̩ ajá o̩de̩ tiwa kó̩
ilé la ní ó s̩ó̩
igbe ni ń mú be̩nu lóròòru
è̩bi ajá o̩de̩ náà kó̩ àìtètèmò̩ náà ni
s̩é wó̩n ní ìfunra lògùn àgbà
àgba wá so̩ ìfunra nù
a rò pé a ní è̩yó̩nú ni
a wí tàìwí
wó̩n kórungbò̩n funfun jo̩
ewú la pè é, àwa ò mò̩ pé ewu ni
wó̩n wá sílé wa
wó̩n wá silè̩ wa
bí wó̩̩n s̩e ń fó̩nu ni wó̩n ń fó̩nwó
Tani yóò rí ìbòji tí yóò tún wò̩rùn
Igbe ajá wo̩n la gbó̩,
àsé ajá inú ìwé niwó̩n
A mú ajá wo̩n délé tán
kí wó̩n bá wa s̩ó̩gbà,
e̩gba ni wó̩n ń fún wa
Wó̩n so̩ òógòn wa domi òjò
wó̩n so̩ è̩jè̩ wa depo tí wó̩n ń dín
E̩ kìlò̩ f'ájá o̩de̩,
kó máà rìn níjù
E̩ kìlò̩ f'ájá o̩de̩
kí igbe rè̩ máà ráns̩é̩ pe kò̩lò̩kò̩lò̩
Àyàfi kí Èdùmàrè tí ń be̩ lókè
kó gbàwá ló̩wó̩ ajá o̩de̩
Tí kò le pe̩ran fún'ni je̩
s̩ùgbó̩n tí ń gba e̩ran ara wa je̩
tó tún fé̩ ba ayé wa jé̩...
AKÉWÌ
TIJANI TAOFEEK B
No comments:
Post a Comment